Jagun Jagun

Akinkunmi Olagunju, Opeyemi Oyewande, Laolu Ajibade, Peter Sadibo, Olufemi Sanni, Babajide Okegbenro, Adegoke Odukoya, Ibrahim Oyetunji

[Chorus]
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀

[Verse 1: Chant]
Olórí-ogun ò gbọdọ̀ kẹ́yìn ogun
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹja tí ń d’abú-omi rú
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹfọ̀n tí ń d’ọ̀dàn rú
Ọ̀kan ṣoṣo Àjànàkú tí ń m’igbó kìji-kìji
Jagun-jagun dé, ọmọ ọba kìí jagun bí ẹrú
Òlọ́ṣọmọ́dìí gba ìbọn lọ́wọ́ ọmọ ojo
Jagun-jagun, afiwájúgbọta, afẹ̀yìngbọfà
Jagun-jagun ò fẹ́rọ̀, alágbára èyàn tí ń fi májèlé ròfọ́
Àlùjànú èyàn tí ń fi ọmọ-odó tayín
Bó ṣe ń bá ọmọdé ṣe, bẹ́ẹ̀ ló ń bágbà ṣe
Kọ̀nàn-kọ̀nàn já tòun tòwú
Jagun-aso, ẹkùn ọkọ òkè!
Arọnimaja ṣáagun!
Ó ṣáagun ṣáagun, ó ṣáagun títí, ohun l’awo Alágbàá`a, èyí tí ó fi ta b’aṣeégún lójú

[Chorus]
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀

Curiosità sulla canzone Jagun Jagun di BANTU (Crew)

Quando è stata rilasciata la canzone “Jagun Jagun” di BANTU (Crew)?
La canzone Jagun Jagun è stata rilasciata nel 2020, nell’album “Everybody Get Agenda”.
Chi ha composto la canzone “Jagun Jagun” di di BANTU (Crew)?
La canzone “Jagun Jagun” di di BANTU (Crew) è stata composta da Akinkunmi Olagunju, Opeyemi Oyewande, Laolu Ajibade, Peter Sadibo, Olufemi Sanni, Babajide Okegbenro, Adegoke Odukoya, Ibrahim Oyetunji.

Canzoni più popolari di BANTU (Crew)

Altri artisti di